KÒKÚMÓ
Aiyé p'égba lóòtó, dúníyàn ní kòrò mogbà,
Sùgbón, aiyé ń dùn ní ìlú òdúndún
Níbi wón gbé ń pé jo je'su àmódún,
Ewà ń be n'ilè èwà láti rí, fún eni tí ó wáa,
Kòkúmó, omo òdò àgbà;
Ìbá wùnmí, k'ádìjo tó àádùn wó n'ílè adùn
Ò bá máìlo, ò bá dúró j'aiyé.
Bàbá sáré sáré, ó s'apá títí, eyín k'orógbó
Ìyá bùrìnbùrìn, gbogbo irun orí d'efun,
Ègbón be'gún l'ówè ebo lo s'íta òrun
Àbúrò ń fi ojú pon'mi ekún láti òdò ìrònú,
Kòkúmó, omo òdò àgbà;
Ìfé eiyelé, ìfé òtító l'afi fé o,
Ò bá máìlo, ò bá dúró sanjó.
Omi èémí yìí l'apon nítorí re
Bóyá wa jé fí bójú, bóyá a jé wè ó mó sáká,
Ebo l'afi ránsé s'ájùlé òrun nítorí re
Bóyá a jé fín, bóyá a jé d'éta òrun gúregúre,
Kòkúmó, omo òdò àgbà;
Nítorí 're a làkàkà, 'torí 're, as'aápón,
Ò bá máìlo, ò bá jé á l'énu opé.
Egbé ń jan'sè món'lè bí eni ìjàlo gbé n'íyàwó
Ogbà ń jan'ra món'lè bí eni ará òrun lù,
Ilè l’osùnsí yìí borogidi bí òkú ìbon
Gbogbo ebí ń fi omijé s'ògbéré ekún,
Kòkúmó, omo òdò àgbà;
Ibi ogbé wà yí o, ilè ire ni
Ò bá máìlo, ò bá dúró tì wá.
#PsalmsInk
#Si_Okan_Kan
© Samuel O. Ogunyinka, (Psalmist).
Comments
Post a Comment